×
Awọn atẹgun idurosinsin lori ẹsin Ọlọhun

Ọrọ isiwaju

Dajudaju gbogbo ẹyin ti Ọlọhun ni, a yin In, a si wa iranlọwọ Rẹ, a si tun wa aforijin Rẹ

A tun wa iṣọ pẹlu Ọlọhun kuro nibi aburu ẹmi wa ati awọn aburu iṣẹ ọwọ wa

Ẹniti Ọlọhun ba ti fi mọ ọna ko si ẹniti o le si i lọna, ẹniti Ọlọhun ba si sọnu ko si ẹniti o le fi i mọna

Mo wa jẹri wipe dajudaju ko si olujọsin fun miran ayafi Allooh ni Oun nikansoso, ko si orogun fun un, mo si tun jẹri wipe dajudaju Anabi Muhammad ẹru Rẹ ni ojiṣẹ Rẹ si ni pẹlu

Lẹyin naa

Dajudaju idurosinsin lori ẹsin Ọlọhun ipinlẹ ti a fẹ fun gbogbo musulumi to jẹ olododo ni, ti o si ni lero lati tọ oju-ọna ti o tọ pẹlu ipinnu ati imọna

Pataki akori yi wa fi ara pamọ sinu awọn alamọri kan ninu rẹ ni:

Iṣesi awujọ eleyi ti awọn musulumi ngbe ibẹ lọwọ bayi, ati awọn oniranran fitina ati awọn nkan ẹtan eleyi ti wọn fi ina rẹ jo ara wọn, ati awọn yodoyindin orisirisi pẹlu awọn iruju eleyi ti o jẹ wipe ni ipasẹ rẹ ni Islaam fi di ajoji

Ni awọn ti wọn dirọ mọ ẹsin fi ni apẹrẹ eemọ - ẹniti o ba gba ẹsin rẹ mu o da gẹgẹbi ẹniti o gba oguna mu ni

Ko wa si iyemeji lọdọ gbogbo ẹniti o ba ni ọpọlọ wipe dajudaju nini bukaata Musulumi teni si awọn atẹgun idurosinsin tobi ju nini bukaata ọmọya rẹ si i nigba aye awọn ẹni isaaju, atipe igbiyanju ti a nfẹ lati fi idi rẹ mulẹ o tobi; latari igba ti o ti bajẹ, ati wiwọn awọn ọmọya, ati lilẹ oluranlọwọ, ati kikere alaranse

Awọn iṣẹlẹ kikoomọ ati isipopada pẹlu iṣẹrikuro wa di nkan ti o pọ, titi ti o fi de aarin awọn ti nṣiṣẹ fun Islaam, ninu ohun ti maa nmu Mulumi bẹru irufẹ awọn aaye yi, ti yio wa maa wa awọn atẹgun idurosinsin lati de ilẹ ifayabalẹ

Sisopọ akori yi pẹlu ọkan; eleyi ti Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – nsọ nipa rẹ pe:

Ọkan ọmọ Anabi Aadam nifi nle ni yiyipada ju ikoko lọ nigbati ooru iho rẹ ba sarajọ

Ahmad gba a wa 6/4 ati Al'Aakim 2/289, o si tun wa ninu tira As'silsilatus Sohiiha 1772

Anabi – ki ikẹ ati ọla maa ba a – tun fi apẹrẹ mii lelẹ fun ọkan, o wa nsọ pe:

Dajudaju wọn sọ ọkan ni ọkan latari yiyipada rẹ, atipe apejuwe ọkan o da gẹgẹbi iyẹ ti nbẹ ni isalẹ igi ti afẹfẹ maa nyi i ni inu sita

Ahmad gba a wa 4/408, o si tun wa ninu tira Sohiihul Jaamih 2361

Ọrọ akọrin kan ti saajun hadiith yi

Wọn o sọ ọmọniyan ni ọmọniyan ayafi latari gbigba rẹ, wọn o si sọ ọkan ni ọkan ayafi latari yiyipada rẹ

Atipe didurosinsin ohun ti nyi pada yi pẹlu atẹgun awọn ifẹnu ati iruju alamọri ti o lewu ni, ti o si bukaata si awọn atẹgun ti o gbopọn ti yio kodi

Awọn atẹgun idurosinsin

Ninu ikẹ Ọlọhun ti O biyi tin O gbọngbọn si wa nipe o salaye fun wa ninu tira rẹ ati ni ori ahọn anabi rẹ ati itan rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – awọn atẹgun ti o pọ fun idurosinsin. Maa darukọ fun ẹ iwọ oluka alapọnle awọn apakan ninu rẹ

Alakọkọ: sisiju si AL'Qur'an

Al'Qur'an ti o tobi ni atẹgun idurosinsin alakọkọ, o si tun jẹ okun Ọlọhun eleyi ti o yi, ati imọlẹ ti o fi oju han, ẹniti o ba di i mu Ọlọhun yio ṣọ ọ, ẹniti o ba tẹle e Ọlọhun o la a, ẹniti o ba pepe si i wọn o fi mọna lọsi oju-ọna ti o tọ

Ọlọhun laa mọlẹ wipe ogongo ohun ti Oun tori rẹ sọ tira kalẹ ni ẹyọ-ẹyọ ni idurosinsin

Ọba ti O ga sọ nigbati nse adapada lori awọn iruju awọn alaigbagbọ

Atipe awọn alaigbagbọ sọ pe kani wọn so Al'Qur'aan kalẹ fun un ni eekanna iyẹn ni lati fi ọkan rẹ rinlẹ, ni a fi ka a fun ọ ni ẹsẹsẹ.

Atipe wọn o lee mu apẹrẹ kankan wa ayaafi ki a mu eyiti o jẹ otitọ wa fun ọ ati eyiti o daa ni alaye

Suuratul Furqoon 32-33

Kilode ti Al'Kurani ṣe jẹ ipinlẹ fun idurosinsin?

Nitoripe o maa ngbin igbagbọ o si maa ṣe afọmọ ẹmi pẹlu mọ Ọlọhun

Toripe awọn aayah yẹn maa nsọkalẹ ni itutu ati ọla lori ẹmi Mumini ti atẹgun fitini o si lee gbe e lọ, ti ọkan rẹ o si balẹ pẹlu iranti Ọlọhun.

Toripe o maa npese fun Musulumi awọn irori ati awọn opo ti o ni alaafia eleyiti yio maa ni ikapa lati ara rẹ lati gbe awọn iṣesi ti o rọkirika rẹ duro

Bakanna ni awọn osuwọn eleyi yio maa jẹ ji o rọrun fun un lati idajọ lori awọn alamọri ti idajọ rẹ o si ni daru, ti awọn ọrọ rẹ o si ni tako ara wọn pẹlu iyapa awọn iṣẹlẹ ati awọn eeyan.

Toripe yio le maa fesi lori awọn iruju eleyi ti awọn ọta Islaam ninu awọn alaigbagbọ ati awọn munaafiki pete rẹ gẹgẹbi awọn apẹrẹ ti nṣẹmi eleyi ti awọn ẹni akọkọ fi oju wina rẹ

Eleyi ni awọn apejuwe

Kinni oripa ọrọ Ọlọhun O biyi ti O gbọngbọn ti o so pe:

Ọlọhun Ọba rẹ o pa ọ ti atipe ko si tun kọ ọ

Suuratud Duha 3

Lori ẹmi ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a.

Kilode ti awọn oṣẹbọ fi sọ wipe: (O ti pa Muhammad ti)

Wo Sọhiihu Muslim pẹlu alaye Alufa wa An-Nawawiy

Atipe kin tun ni ilapa gbolohun Ọlọhun ti O biyi ti O gbọngbọn ti o sọ pe:

Ahọn ti wọn ṣẹri lọ ba wipe oun ni nkọ Anabi ahọn ti ko le ka ni atipe eleyi ti a sọkalẹ fun un yi ahọn larubawa ti o fi oju han ni

Suuratun Nah'l 103

Nigbati awọn keferi Quraish pe apemọra wipe dajudaju Muhammad – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – abarapa ni ẹniti nkọ ọ, atipe ọwọ kanlekanle ara roomu ti o wa ni Makkah ni o ti ngba Al'kuraani.

Atipe kin tun ni ilapa gbolohun Ọlọhun ti O biyi ti O gbọngbọn ti o sọ pe:

Ẹ gbọ o inu fitina gan-an ni wọn ko si

Suuratut Taobah 49

Ninu ẹmi awọn Mumini nigbati Munaafiki naa sọ pe:

Yọnda fun mi ma si ko fitina ba mi?

ṣe kii ṣe idurosinsin lori idurosinsin, atipe idi awọn ọkan ti o gbagbọ ni amure, oati adapada lori awọn iruju, ati dida awọn onibajẹ lakẹ.

Bẹẹ lo ri mo si tun Ọlọhun mi ṣẹri

Ninu ohun ti nṣeni ni eemọ nipe dajudaju Ọlọhun ṣe ni adehun fun awọn Mumini nibi iṣẹri pada wọn lati Udaibiyah pẹlu ọrọ ogun ti o pọ ti wọn o ri, oun naa ni ọrọ ogun Khaibar

Atipe dajudaju yio ṣe e fun wọn, ati dajudaju wọn yio lọ sibẹ lai si elomii pẹlu wọn

Atipe awọn Munaafiki o maa wa ki awọn o tẹle wọn lọ

Atipe dajudaju awọn Musulumi o maa sọ wipe ẹ o lee tẹle wa lọ

Atipe dajudaju wọn yio maa taku wọn lẹniti wọn gbero lati yi ọrọ Ọlọhun pada

Atipe dajudaju wọn yio maa sọ fun awọn Mumini wipe ẹ nṣe keeta wa ni o, Ọlọhun wa fun wọn lesi pẹlu gbolohun Rẹ ti o wi pe:

Sugbọn wọn ẹniti kọ gbọ agbọye ayaafi diẹ

Lẹyinna ni gbogbo eleyi wa nṣẹlẹ loju awọn Mumini ni ipele ipele ati ni igbesẹ igbesẹ ati ni gbolohun ni gbolohun

Latari eleyi ni a fi ni ikapa lati mọ iyatọ ti nbẹ laarin awọn ti wọn so iṣẹmi aye wọn pọ mọ Al'kuraani ti wọn si siju si i ni kika ati iha, ni alaye ati ni ironusi, ninu rẹ ni wọn ti nlọ, ibẹ ni wọn si nṣẹri pada si, ati laari awọn ti wọn ṣe ọrọ ẹda ni ọpọ akolekan wọn ati airojuraye wọn

Atipe o ma ṣe fun awọn ti nwa mimọ ti wọn si nfun Al'kuraani ati alaye rẹ ni ipin ti o tobi ni nkan ti wọn wa.

Eleekeji

Didunni mọ ofin Ọlọhun ati iṣẹ rere

Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:

Ọlọhun maa nfi awọn ti wọn ni igbagbọ rinlẹ pẹlu gbolohun ti o durosinsin ni ile-aye ati ọjọ ikẹhin Ọlọhun si maa nsọ awọn alabosi nu, Ọlọhun si maa nṣe nkan ti o ba wu ﷻ‬

Suuratu Ibrọọhim 27

Alufa wa Qotaadah sọ pe:

Ama ile-aye yio fi wọn rinlẹ pẹlu daada ati iwa rere, atipe ni ọjọ ikẹhin ni inu saare

Atipe bẹ na ni wọn ṣe gba a wa lati ọdọ ogọọrọ awọn ẹni isaaju

Tafseerl Qur'aanil Adhiim ti Alufa wa Ibnu Kathiir 3/421

Ọlọhun ti O mọ tun sọ pe :

Atipe kani wọn ṣe ohun ti wọn nki wọn nilọ pẹlu rẹ ko ba loore fun wọn ti yio si tun jẹ idurosinsin ti o le

Suuratun Nisaai 66

Iyẹn nipe lori ododo

Eleyi si fi oju han, bibẹẹkọ njẹ a le maa reti idurosinsin lati ọdọ awọn ọlẹ awọn ti wọn maa npa awọn iṣẹ daada ti nigbati fitina ba pẹ lori wọn ti wahala si mi wọn titi

Sugbọn awọn ti wọn ni igbagbọ ti wọn si tun ṣiṣẹ rere Ọba wọn o fi wọn mọna ti o tọ pẹlu igbagbọ wọn

Tori naa Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti maa ndunni mọ awọn iṣẹ rere, atipe iṣẹ ti o si nifẹ si julọ ni eyiti ko duro koda ki o kere

Atipe awọn saabe rẹ jẹ ẹniti o ṣe wipe ti wọn ti ṣe iṣẹ kan won yio fi idi rẹ mulẹ. Atipe Aaisha – ki Ọlọhun yọnu si i – jẹ ẹniti o ṣe wipe ti o ba ti ṣe iṣẹ kan yio dunni mọ ọn

O jẹ ẹniti maa nsọ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pe:

Ẹniti o ba dunni mọ rakaah mejila kan, alujannah ti jẹ dandan fun un

Sunnan Tirmidhi 2/273, o wa sọ pe: hadith yi daa tabi o ni alaafia

O si tun wa ninu Sohiihun Nasaa'i 1/388, ati Sohiihut Tirmidhi 1/131.

Oun naa ni awọn naafila ẹyin awọn irun ọranyan

Atipe ninu hadith qudusi

Ẹru Mi o ni yẹ ko ni gbo lẹniti yio maa sunmọ Mi pẹlu awọn naafila titi ti maa fi nifẹ rẹ

Bukhaari lo gba a wa, wo inu tira Fat'hul Baari 11/340

Ẹlẹẹkẹta

Imaa ronu si awọn itan awọn anabi Ọlọhun ati imaa kọ ẹkọ rẹ, fun awokoṣe ati iṣiṣẹ tọ

Atipe ẹri lori iyẹn ni gbolohun Ọlọhun ti o sọ pe:

“Atipe gbogbo rẹ lati pa nitan fun ọ ninu iro awọn ojiṣẹ to saaju leyiti yio fi ọkan rẹ balẹ atipe o si ti de wa ba ọ ninu eyiti a sọ yi ododo ati isiti ati iranti fun awọn olugbagbọ ododo".

Suratul Huud 120

Atipe wọn o sọ awọn aayah yi kalẹ ni igba aye Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – fun ere ati apara.

Bi kii ṣe wipe fun erongba kan ti o tobi, oun naa ni lati fi ọkan ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ati awọn Muumuni rinlẹ.

Ti o ba wa woye daada irẹ ọmọ-iya mi si gbolohun Ọlọhun ti O biyi ti O si gbọnngbọn ti o sọ pe:

Wọn sọ pe ẹ dana sun un ki ẹ si ran awọn Ọlọhun yin lọwọ toba jẹ wipe ẹ le se bẹ ẹ.

“Awa sọ wipe irẹ ina, di tutu ati ọla fun Ibrahim"

“Wọn wa gbero aburu ro o, a si sọ wọn di ẹni iparun".

Suuratul Anbiyaah 68-70

Ibnu Abbaas sọ pe:

Gbolohun ti Anabi Ibrahim sọ kẹhin nigbati wọn ju u si inu ina ni: Hasbiyallaahu wa nih'mal wakeel.

Al'fat'hu 8/22

Ṣe oo kẹfin itumọ kan ninu awọn itumọ idurosinsin niwaju ijẹgaba leni lori ati ifiyajẹni, ti nwọle si ẹmi rẹ nigbati o nwoye si itan yii?

Ti o ba wa ronu si gbolohun Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn ninu itan Anabi Musa, ti o sọ pe:

“Nigbati awọn mejeeji fi oju kan ara wọn, awọn eeyan Anabi Musa sọ pe dajudaju wọn ti le wa ba".

“O wa sọ pe: ko ri bẹ ẹ dajudaju Ọba mi nbẹ pẹlu mi ti yio si se amọna mi".

Suuratu Shuarooh, 61-62

Ṣe oo kẹfin itumọ mii ninu awọn itumọ idurosinsin nibi iṣe alabapade awọn ti nwa eeyan kiri, ati idurosinsin ni awọn asiko ilekoko laarin ariwo awọn ti ara n ni , ti iwọ si nwoye si itan yi?

Ti o ba woye si itan awọn opidan Firiaona, iyẹn ni apẹrẹ eemọ fun awọn ikọ ti wọn fi ẹsẹ mulẹ lori ododo lẹyin igbati o ti fi oju han.

Se oo ri itumọ kan ti o tobi ninu awọn itumọ idurosinsin eleyi ti maa nrinlẹ ninu emi niwaju idẹruba alabosi lẹniti o nsọ pe:

O sọ pe ẹ gba a gbọ siwaju ki nto yọnda fun yin dajudaju oun ni agba yin ti o kọ yin ni idan, niti paapa maa ge awọn ọwọ yin ati awọn ẹsẹ yin ni pasipayọ maa si kan yin mọ awọn kukute ọpẹ ẹẹ si mọ daju ẹniti o buruju niya ninu wa ti o si sẹku.

Suuratu Toha 71

Ifẹsẹrinlẹ awọn perete ti wọn ni igbagbọ ti o si jẹ wipe iṣẹripada kekere kan o ropọ mọ ọn, ti wọn wa nsọ pe:

Wọn sọ wipe a o le gbe ọla fun ọ lori ohun ti o ti de wa bawa ninu awọn ohun ti o fi oju han, ati lori Ẹniti O da wa, dajọ ohun ti o ba wu ọ lati da, dajudaju aye yi nikan ni idajọ rẹ mọ.

Suuratu Toha 72

Atipe bakannaa ni itan olugbagbọ ododo ninu suuratu yaasin ati olugbagbọ ododo ninu awọn ọmọlẹyin Firiaona ati awọn as'aabul ukh'duud ati eyiti o yatọ si i, ti o si sunmọ wipe idurosinsin ni o jẹ ohun ti o tobi julọ ninu awọn ẹkọ gbogbo rẹ patapata.

Ẹlẹẹkẹrin

Adua

Ninu awọn iroyin awọn ẹrusin Ọlọhun ti wọn ni igbagbọ ni wipe wọn maa nda oju kọ Ọlọhun nibi adua wọn wipe ki o fi ẹsẹ wọn rinlẹ.

“Irẹ Ọlọhun wa ma yẹ awọn ọkan wa lẹyin igbati O ti fi wa mọna".

“Ọlọhun wa da suuru le wa lori, ki O si fi ẹsẹ wa rinlẹ"

Nigbati o jẹ wipe

awọn ọkan awọn ọmọ Anabi Aadam wa laarin ọmọ-ika meji ninu awọn ọmọ-ika Ọlọhun ti njẹ Ar'Rahmaan ti o wa da gẹgẹbi ọkan kan, ti O si ndari rẹ si ibiti O ba fẹ.

Imam Ah'maad ati Muslim lo gba a wa lati ọdọ ọmọ Umar leyiti wọn gbe e lọ si ọdọ Anabi.

Wo Muslim pẹlu Shar'hun Nawawi 16/204

Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti o maa nsọ lọpọlọpọ pe:

“Mo pe Irẹ Ọba ti maa nyi awọn ọkan pada, fi ọkan mi rinlẹ lori ẹsin Rẹ".

Tirmidhi lo gba a wa lati ọdọ Anas ni eyi ti a gbe lọ si ọdọ anabi, Tuh'fatul Ah'wasiyy 6/349, o si tun wa ninu Sohiihul Jaamih

Ẹlẹẹkarun

Iranti Ọlọhun

O wa ninu awọn okunfa idurosinsin ti o tobi ju.

Woye si asopọ ti o wa laarin alamọri meji ti o wa nibi gbolohun Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn ti o sọ pe

“Mo pe ẹyin ti ẹ gba Ọlọhun gbọ ti ẹ ba ti pade ikọ kan ki ẹ duro sinsin ki ẹ si ranti Ọlọhun ki ẹ le baa jere".

Suuratul Anfaal 45

O si se e ninu ohun ti o tobi ti maa ran ẹni lọwọ lori didurosinsin nibi ijagun si oju ọna Ọlọhun.

Atipe woye si ara awọn ijọ faaris ati roomu bi ohun ti wọn bukaata si ju se ja wọn kulẹ.

Ohun ti n bẹ laarin ami ọrunfa mejeeji, a ya a ninu ọrọ Ibnul Qoyyim – ki Ọlọhun kẹ ẹ - ninu tira Ad-Daa' wad-Dawaah.

Pẹlu kekere onka ati ipese awọn oluranti Ọlọhun.

Atipe pẹlu kini Anabi Yuusuf fi wa akunlọwọ lori idurosinsin ni iwaju arabinrin ti o ni ipo ti o si ni ẹwa nigbati o pe e fun ara rẹ?

Ṣe kii ṣe wipe o ko sinu odi iṣọ ifi Ọlọhun wa iṣọra, ti awọn igbi ọmọ-ogun adun si run nigbati o se alabapade odi iṣọ Rẹ ni?.

Bayi ni awọn iranti ṣe nṣiṣẹ nibi idurosinsin awọn Muumini.

Ẹlẹẹkẹfa

Imaa se ojukokoro lori ki Musulumi o maa tọ ọna ti o ni alaafia

Atipe ọna kan soso ti o ni alaafia ti o si pọndandan fun Musulumi ki o tọ ọ oun naa ni oju-ọna awọn Ah'lus Sunnah wal Jamaaha, oju-ọna awọn ijọ ti wọn ti kun lọwọ, ati awọn ikọ ti wọn ti yege, awọn ti wọn ni adisọkan ti o mọ ati ilana ti o tọ, ati awọn olutẹle sunnah ati ẹri, ati dida yatọ si awọn ọta Ọlọhun ati imaa ya kuro lara awọn ẹni ibajẹ.

Ti o ba wa fẹ mọ bi idurosinsin yi ṣe niye lori si, ki o yaa woye ki o si bi ara rẹ leere pe: kilo fa a ti ọpọlọpọ awọn asaaju ati awọn ti wọn tele wọn se nu ti wọn daamudaabo, ti ẹsẹ wọn o si rinlẹ lori oju-ọna ti o tọ, ti wọn o si ku si ori rẹ?.

Tabikẹ ti wọn tiẹ de ibẹ lẹyin igbati wọn lo ọpọlọpọ ọjọ-ori wọn, ti wọn si ra awọn asiko ti o tobi ninu iṣẹmi aye wọn lare?

Oo wa ri ọkan ninu wọn ti yio maa si kaakiri laarin awọn agbegbe adadaalẹ ati anu, ninu imọ irori (Fal'safa) lọ sibi imọ ọrọ (Il'mul Kalaam), ati imọ Al-Ih'tizaal lọ sibi imaa yi iroyin Ọlọhun pada, ati nibi imaa yi itumọ ọrọ Ọlọhun pada lọ sibi imaa ṣe afiti rẹ lọna ibajẹ, ati imaa sọ pe iṣẹ ko si ninu igbagbọ, ati lati oju ọna suufi kan bọ si omiran

Bayi ni awọn aladadaalẹ ṣe maa ndaamu-daabo, wa woye si bi wọn ṣe ṣe idurosinsin leewọ fun awọn onimimọ ọrọ (Ah'lul Kalaam) ni ọjọ iku wọn, ni awọn asiwaju rere fi sọ pe:

Ẹniti fi npọ ju ni ṣiṣe iyemeji ni asiko iku ni awọn onimimọ ọrọ (Ah'lul Kalaam).

Sugbọn ronu ki o si ṣe ariwoye, njẹ o ri ọkan ninu awọn Ah'lus Sunnah wal Jamaaha ti o ṣẹri kuro ni oju-ọna rẹ niti ibinu lẹyin ti o ti mọ ọn ti o si ti gbọ ọ ye ti o si ti tọ ọ?.

O wa le gbe e ju silẹ latari awọn ifẹ-inu ati awọn adun, tabi awọn iruju ti o de ba laakai rẹ ti o lẹ, sugbọn ko le gbe e ju silẹ latari wipe o wa ri eyiti o dara ju u lọ tabi latari wipe ibajẹ rẹ han si i.

Atipe ohun ti yio maa ṣe ẹri eleyi ni ibeere ti Hiraq'l beere lọwọ Abu Suf'yaan nipa awọn ti ntẹle Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a –

Hiraq'l sọ fun Abu Suf'yaan pe:

Njẹ ẹnikẹni ninu wọn koomọ lẹniti nbinu si ẹsin rẹ lẹyin igbati o ti wọ inu rẹ bi?.

Abu Suf'yaan sọ pe: rara

Lẹyin naa ni Hiraq'l wa sọ pe:

Bẹẹ gẹlẹ ni igbagbọ nigbati awọn ọkan ba ti ropọ mọ imọlẹ rẹ.

Bukhaari lo gba a wa, Al-Fat'h 1/32

A gbọ ni ọpọ igba nipa awọn agbalagba ti wọn nṣi kiri ninu awọn ile adadaalẹ ati nipa awọn mii ti Ọlọhun fi wọn mọna ti wọn si gbe ibajẹ ju silẹ lọ si ibi oju-ọna awọn Ah'lus Sunnah wal Jamaaha lẹniti nbinu si oju-ọna wọn alakọkọ, sugbọn njẹ a gbọ idakeji rẹ ri?.

Ti o ba wa n fẹ idurosinsin, o di ọwọ rẹ imaa tẹle oju-ọna awọn Muumini.

Ẹlẹẹkeje

Rire

Rire diẹ diẹ ti o nii ṣe pẹlu imọ nipa igbagbọ ti n tani ni ologo jẹ okunfa ipilẹ ninu awọn okunfa ifẹsẹmulẹ

Rire nipa igbagbọ: eyi ti o maa n ta ọkan ji pẹlu ibẹru ati agbiyele ati ifẹ, eyi ti n tako ọgbẹlẹ ti o jẹ jade latara jijina si ọrọ inu Kuraani ati Sunnah, ati diduro lori ọrọ ti awọn eeyan ba sọ

Rire nipa imọ: eyi ti o ni ẹri ti o ni alaafia ti o tako titẹle ọrọ awọn onimimọ ti a bu ẹnu atẹ lu"

Rire ti n tani ni ologo: eyi ti ko ni ibatan pẹlu oju ọna awọn ọdaran, ti o si n ṣe iwadi nipa ero awọn ọta Islam, ti o si tun n sọ nipa ohun ti n ṣẹlẹ ni ayika pẹlu agbọye ati atunṣe, eyi ti o tako aiba awujọ ṣe ati didadi si ayika kekere

Rire diẹ diẹ: eyi ti yoo maa lọ pẹlu Musulumi diẹ diẹ, yoo maa mu u ga ni oju ọna pipe rẹ pẹlu erongba ti a wọn, eyi ti o tako ṣiṣe nkan lai gbero rẹ tẹlẹ ati aini ifarabalẹ tii ba iṣẹ jẹ"

Ki a le baa mọ pataki ipilẹ yii ninu awọn ipilẹ iduro sinsin, ki a pada si itan igbesi aye ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun ma aba a- ki a wa bi ara wa leere pe:

Kini ipilẹ iduro sinsin awọn saabe Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun ma aba a- ni ilu Mẹka ni asiko ti wọn n fi suta kan wọn?

Bawo ni Bilal ati Khabaab ati Mus'hab ati awọn araale Yaasir ati awọn miran ninu awọn ti ko ni agbara titi de ori awọn agbaagba ninu awọn saabe, ṣe duro sinsin ni asiko ti wọn si wọn mọle ni aaye kan ti o wa laarin oke meji, ati asiko inira miran?

Njẹ o rọrun ki iduro sinsin wọn yii waye lai si ẹkọ ti o jindo lati ọdọ Anọbi, eyi ti o sọ wọn di abiwa rere?

Ẹ jẹ ki a fi saabe kunrin kan ṣe apẹrẹ gẹgẹbi Khabbaab ọmọ Al-Aratt- ki Ọlọhun yọnu si i- ti olowo rẹ maa n jo irin ni ina titi yoo fi pọn, lẹyin naa yoo da a dubulẹ sori rẹ lai fi aṣọ Kankan bo ẹyin rẹ, titi ti ọra ara rẹ yoo fi pa ina naa, kini o jẹ ki o le ṣe suuru lori gbogbo eleyii?

Ti Bilaal si wa ni abẹ apata ninu oorun ti o gbona gidi, ti wọn si de Sumayyah ni sẹkẹsẹkẹ

Ibeere kan ti o jẹ jade latara nkan miran ti o ṣẹlẹ ni igba ti Anọbi wa ni Mẹdina ni pe, tani o duro ti Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ni ogun Hunayn nigba ti ọpọlọpọ awọn Musulumi fidi rẹmi?

Njẹ awọn ti wọn ṣẹṣẹ gba Islam ni ati awọn ti wọn gba Islam lẹyin ti wọn gba ilu Mẹka, awọn ti wọn ko ri asiko ti o to lati fi kọ ẹkọ ni ile ẹkọ Anọbi, ati awọn ti ọpọlọpọ wọn jade lọ jagun nitori ọrọ ogun ni bi?

Ko ri bẹẹ, dajudaju ọpọlọpọ awọn ti wọn duro ti Anọbi ni awọn ẹni ẹsa ti wọn gba ẹkọ ti o tọ lati ọwọ ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a)

Ti ko ba si ẹkọ Kankan ni, njẹ awọn wọnyi a duro bi?

Ẹlẹẹkẹjọ

Fifi aya balẹ si oju ọna naa

Ko si iyemeji nibi pe bi aya ba ṣe n balẹ si oju ọna ti Musulumi n tọ si, ni iduro sinsin rẹ yoo ṣe maa ni agbara si. Eleyi ni awọn atẹgun kan, ninu rẹ ni:

Mimọ wipe ọna ti o tọ ti o n tọ- irẹ ọmọ iya mi- kii ṣe tuntun, kii sii ṣe pe asiko rẹ ni iru rẹ ṣẹṣẹ waye,

Bi kii ṣe pe ọna ti o ti pẹ ni, ti awọn ti wọn ṣaaju rẹ ti tọ ninu awọn anọbi ati awọn siddiikuun ati awọn onimimọ ati awọn ti wọn ku iku ṣẹidi ati awọn ẹnirere, eyi a jẹ ki o mọ pe o o ki n ṣe ajoji ni oju ọna naa, ti ipa aayun rẹ yoo di ifararo, ti ibanujẹ rẹ yoo di idunu; tori pe o mọ pe awọn yẹn pata ọmọ iya rẹ ni wọn ni oju ọna naa.

Mimọ pe eeyan ti di ẹni ẹsa

Ọlọhun ti O niyi ti O gbọnngbọn sọ pe:

Ọpẹ ni fun Ọlọhun, alaafia ki o maa ba awọn ẹru Rẹ ti O sa lẹsa

An-Nam'l/59

O sọ pe:

“Lẹyin naa A mu awọn ti A sẹsa ninu awọn ẹru Wa jogun Iwe naa"

Faatir/32

O sọ pe:

“Gẹgẹ bẹẹ ni Ọlọhun rẹ ṣe sẹsa rẹ ti O si n fi itumọ awọn ọrọ naa mọ ọ"

Yuusuf/6

Gẹgẹbi Ọlọhun ṣe sẹsa awọn anọbi, gẹgẹ bẹẹ naa ni awọn ẹni ire naa ṣe ni ipin ninu sisẹsa naa, oun naa ni ohun ti wọn jogun rẹ

Bawo ni o ṣe maa ri lara rẹ ti Ọlọhun ba da ọ ni nkan ti ko ni ẹmi, tabi ẹranko, tabi keferi, tabi olupepe si adadaalẹ, tabi pooki, tabi Musulumi ti kii pepe si Islam, tabi olupepe ni oju ọna ti o kun fun aṣiṣe?

Ṣe o o ri i pe mimọ ti o mọ pe Ọlọhun sa ọ lẹsa ti O si ṣe ọ ni olupepe ninu ahlu sunnah wal-Jamaa'ah, eyi wa ninu awọn okunfa iduro sinsin rẹ ni oju ọna rẹ ni?

Ẹlẹẹkẹsan

Pipepe si ti Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn

Ti ẹmi o ba maa lọ maa bọ, yoo bajẹ, ti ko ba maa gbera ni, yoo bajẹ

Ninu awọn aaye ti o tobi ju ti ẹmi ti maa n gbera sọ ni: pipepe si ti Ọlọhun, oun ni iṣẹ awọn ojiṣẹ, oun ni sii maa n la ẹmi kuro nibi iya, inu rẹ ni agbara ti maa n tu jade ti iṣẹ si maa n gba ṣiṣe

“Nitori eyi, maa pe ipe, ki o si duro deede gẹgẹbi a ti pa ọ laṣẹ"

Nkan ti a ba ti n sọ nibẹ pe lagbaja ko lọ siwaju ko si lọ sẹyin, ko ba oju mu; toripe ti o o ba ti ko airoju ba ẹmi pẹlu titẹle ti Ọlọhun, ẹmi yoo ko airoju ba ọ pẹlu iyapa ti Ọlọhun

Igbagbọ maa n lekun o si maa n dinku

Ipepe si oju ọna ti o tọ pẹlu nina asiko, ati ironu jinlẹ, ati ilakaka ara, ati didantọ ahọn, ni ọna ti ipepe yoo di ohun ti o jẹ Musulumi ni ogun, eleyii yoo bẹ igi dina igbiyanju setaani lati sọ ni nu ati lati da fitina silẹ

Ni afikun si eyi ni ipenija ti n doju kọ olupepe ninu ẹmi rẹ ni oju ọna ipepe rẹ latari awọn idiwọ ati awọn alagidi, ati awọn obilẹjẹ, eyi yoo mu ki igbagbọ rẹ o lekun ti awọn origun rẹ yoo si ni agbara si.

Yatọ si laada nla ti n bẹ nibi ipepe si oju ọna Ọlọhun, ipepe yoo tun jẹ atẹgun kan ninu awọn atẹgun iduro sinsin ati aabo kuro nibi ifasẹyin

Toripe ẹniti ba n gbeja koni, ko ni bukaata si olugbeja

Ọlọhun si maa n wa pẹlu awọn olupepe, O maa n mu wọn duro, O si maa n fi ẹsẹ wọn le ọna ti o tọ. Olupepe da gẹgẹbi dokita ti n gbogun ti aisan pẹlu iriri rẹ ati imọ rẹ, pẹlu bi o ṣe n gbogun ti i lara ẹlomiran, oun gan funra rẹ ni o maa jina si kiko aisan ju

Ẹlẹẹkẹwa

Rirọgbayika awọn ipilẹ tii muni duro sinsin

Lara awọn iroyin awọn ipilẹ yii ni ohun ti anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- sọ fun wa pe:

“Dajudaju awọn eeyan kan n bẹ ninu ẹda ti wọn jẹ kọkọrọ fun oore ti wọn si jẹ agadagodo fun aburu"

Hadiisi ti o dara ni, Ib'nu Maajah ni o gba a wa lati ọdọ Anas ni eyi ti a gbe de ọdọ anabi 237, Ib'nu Abi Asim naa tun gba a wa ninu tira “As-Sunnah" 1/127, tun wo inu “As-Sil'silah As-Saheehah" 1332

Ṣiṣe awari awọn onimimọ ati awọn ẹniire ati awọn olupepe ti wọn ni igbagbọ, ki eeyan si rọgba yi wọn ka, eyi maa n kun ni lọwọ lati duro sinsin

Awọn fitina ti ṣẹlẹ ri ninu itan Islam ti Ọlọhun si mu awọn Musulumi duro latara awọn eeyan kan

Lara rẹ ni ohun ti Aliyy ọmọ Al'Madiiniy sọ- ki Ọlọhun kẹ ẹ- pe:

“Ọlọhun fun ẹsin ni agbara pẹlu Abubakr As-Sidiik ni ọjọ Riddah, ati pẹlu imam Ah'mad ni ọjọ Mih'nah"

Ronu jinlẹ si ohun ti ib'nul Qayyim- ki Ọlọhun kẹ ẹ- sọ nipa Ib'nu Taymiyah nipa imuni duro sinsin:

Ti ibẹru ba ti lekoko mọ wa, ti awọn eeyan ti n ro ero aburu si wa, ti ilẹ si ti fun pinpin mọ wa, a maa wa ba a, ti a ba si ti ri i, ti a si gbọ ọrọ rẹ, gbogbo nkan ti o n ṣe wa maa lọ ni, ti yoo si pada di idunu ati agbara ati amọdaju ati ifayabalẹ, mimọ fun Ọlọhun ti O mu awọn ẹda Rẹ ri Alujanna Rẹ siwaju pipade rẹ, ti O si ṣi awọn ilẹkun rẹ fun wọn ni ile aye, O si fun wọn ninu oorun rẹ ohun ti yoo jẹ ki wọn o lo gbogbo agbara wọn lati wa Alujanna naa ati lati ṣe idije lọ sibẹ

Al'waabilus-Sayyib, oju ewe 97

Ibi ni ijẹ ọmọ iya ninu Islam yoo ti han gẹgẹbi ipilẹ fun imuduro sinsin, awọn ọmọ iya rẹ ti wọn jẹ ẹniire ati awọn ẹniti a n wo kọṣe, ati awọn olureni, awọn ni wọn a ran ẹ lọwọ ni oju ọna naa, awọn si ni origun ti o lagbara ti o le sa tọ, ti wọn a si mu ọ duro sinsin pẹlu awọn ami Ọlọhun ati ọgbọn ti n bẹ ni ọdọ wọn

“Maa wa pẹlu wọn, ma ṣe maa dawa ki setaani ma baa ja ọ gba; toripe agutan ti o ba takete ni ikoko maa njẹ"

Ẹlẹẹkọkanla.

Fifi aya balẹ si aranṣe Ọlọhun, ati pe ọjọ ọla ti Islam nii ṣe

A ni bukaata si iduro sinsin lọpọlọpọ nigba ti aranṣe ba pẹ ki o to de, ki ẹsẹ ma baa yẹ gẹrẹ lẹyin ti o ti rinlẹ tan

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:

“Melo-melo ni awọn anabi ti wọn ti ja pẹlu ọpọlọpọ awọn olusin Oluwa. Wọn ko jura silẹ nipa ohun ti o ba wọn ni oju ọna ti Ọlọhun, wọn ko si se aarẹ, bẹẹ wọn ko si sọ ara wọn di yẹpẹrẹ. Ọlọhun si fẹran awọn onisuuru"

“Ọrọ wọn ko ju pe wọn wipe: Oluwa wa, dari awọn ẹṣẹ wa jin wa, ati aṣeju ninu iwa wa, ki O si mu ẹsẹ wa duro sinsin, ki O si gbe wa leke awọn alaigbagbọ eniyan"

“Ọlọhun si fun wọn ni ere aye yii ati eyi ti o dara julọ ninu ere ọjọ ikẹyin. Ọlọhun fẹran awọn ti n ṣe rere"

Aal Im'raan 146-148

Nigba ti ojiṣẹ Ọlọhun fẹ mu awọn saabe rẹ ti wọn n fi iya jẹ duro sinsin, o fun wọn ni iro pe ọjọ ọla ti Islam nii ṣe, ni awọn asiko ijiya ati adanwo yii, kini o sọ?

“O wa ninu hadiisi Khabbab ti a gbe de ọdọ anabi lati ọdọ Bukhari pe:

“Ọlọhun yoo pe alaamọri yii titi ti arinrin-ajo yoo fi rin lati San'aa titi de Had'ramaot, ti ko nii bẹru nkankan ayafi Ọlọhun ati ikoko lori ẹran rẹ"

Bukhaari lo gba a wa, wo inu tira Fat'hul Baari 7/3165

Ṣiṣe afihan awọn hadiisi iro idunu fun awọn ọdọ pe ọjọ ọla ti Islam nii ṣe, o ṣe pataki lati fi re wọn lori iduro sinsin

Ẹlẹẹkejila

Mimọ paapaa irọ, ki eeyan ma si gba ẹtanjẹ pẹlu ẹ

Nibi gbolohun Ọlọhun ti O niyi ti O gbọnngbọn, ti O sọ pe:

“Ma ṣe jẹ ki yọ-sibi-yọ-sọhun awọn alaigbagbọ ninu awọn ilu tan ọ jẹ"

Aal Im'raan/196

Lati mu ibanujẹ awọn Mumini lọ, ati lati mu wọn duro sinsin

Ninu gbolohun Ọlọhun ti O biyi ti O si gbọngbọn:

“Eyi ti o jẹ ifofo, yoo rẹ danu bi ohun ti ko ni laari"

Ar-Rah'd 17

Ariwoye lo jẹ fun awọn ti wọn ni ọpọlọ lati ma bẹru irọ ati ki wọn ma jupajusẹ silẹ fun un.

Atipe ninu oju-ọna Al'Qur'an ni imaa yẹpẹrẹ awọn onirọ, ati imaa tu awọn erongba ati atẹgun wọn sita.

"Bayi ni A o maa ṣe alaye awon ami naa ati ki oju ọna awọn ẹlẹṣẹ le han"

"الأنعام /55

Titi wọn o fi nii gba awọn musulumi mu lojiji, titi wọn o si fi mọ ibiti wọn n gba wọle si Islaam lara.

Atipe melo-melo ni a ti gbọ melo-melo ni a si ti ri ninu awọn ikọ ti wọn ti subu ati awọn olupepe ti ẹsẹ wọn ti yẹgẹrẹ, ti wọn si padanu iduro sinsin nigbati wọn wọle si wọn lara nibi ti wọn o ti lero latara aimọ awọn ọta wọn

Ẹlẹẹkẹtala

Imaa ko awọn iwa ti o le ran ọmọniyan lọwọ lori idurosinsin jọ.

Atipe eyiti o ga ninu ẹ ni suuru, atipe o wa ninu hadith Sohiihain

Wọn o fun ẹnikankan ni ẹbun kan ti o loore ti o si gba aaye to suuru

Bukhaari gba a wa ninu tira Zakaat – abala ti o sọ nipa ikoraro nibi ibeere, ati Muslim ninu tira Zakaat – abala ti o sọ nipa ọla ti nbẹ fun ini amojukuro ati suuru.

Atipe suuru ti o fi nle ju nbẹ nibi ajalu akọkọ, ti nkan ti ọmọniyan o ba lero ba ṣẹlẹ si i, ifasẹyin a ṣẹlẹ ti idurosinsin ṣi maa yẹ gẹrẹ nigbati ko ba si suuru.

Woye si nkan ti Ibnul Jaoziy sọ - ki Ọlọhun kẹ ẹ- pe:

Mo ri agbalagba kan ti ọjọ ori rẹ sunmọ ọgọrin, ti o si maa nduni mọ jamaha, ni ọmọ ọmọbinrin rẹ ba ku, ni o wa sọ pe: ko tọ fun ẹnikẹni lati ṣe adua, toripe ko ki njẹ ipe adua. Lẹyinna ni o tun wa sọ pe: dajudaju Ọlọhun ti O ga maa n ṣe agidi ko fi ọmọ Kankan silẹ fun wa.

ATH'THABAAT IN'DAL MOMAAT ti Ibnul Jaoziy, oju-ewe 34

Ọlọhun ga tayọ gbolohun rẹ to wi ni giga ti o tobi

Nigbati adanwo kan awọn musulumi ni oju ogun Uhud ti wọn o si rankan iru adanwo naa; toripe Ọlọhun ṣe adehun aranṣe fun wọn, Ọlọhun wa kọ wọn ni ẹkọ ti o le pelu awọn ẹjẹ ati awọn to kuku oju ogun.

“Nigbati adanwo kan yin lati ọwọ awọn keferi ti ẹyin naa si ti fi ilọpo meji rẹ kan wọn, ẹ wa sọ pe nibo ni eleyi ti wa, sọ pe lati ọdọ ara yin ni".

Aal Im'raan/165

Kini nkan ti o wa lati ọwọ ara wọn?

“Ẹ ni ijakulẹ nigbati ẹ ṣe ifanfa lori alamọri ẹ si tun yapa lẹyin igba ti O ti mu yin ri ohun ti ẹ nfẹ, o nbẹ ninu yin ẹniti nfẹ aye".

Ẹlẹẹkẹrinla

Asọtẹlẹ ẹniire

Ti fitina ba ṣẹlẹ si musulumi ti Ọba rẹ si dan an wo lati fi gbe e yẹwo, ohun ti yio jẹ ọkan lara awọn irinṣẹ idurosinsin ni ki Ọlọhun yan ẹniire ti i, ti yio maa ṣe isiti fun un ti yio si maa fi ẹsẹ rẹ rinlẹ, ti yio si jẹ awọn gbolohun ti Ọlọhun a jẹ ki o se anfaani, ti yio si jẹ ki awọn igbesẹ rẹ duro tọ.

Atipe awọn gbolohun yi maa jẹ eyiti yio kun fun irannileti nipa Ọlọhun, ati ṣiṣe alabapade Rẹ, ati alujanna Rẹ, ati ina Rẹ

Atipe gba awọn apẹrẹ wọnyi irẹ ọmọ-iya mi ninu itan aye Imaam Ahmad – ki Ọlọhun kẹ ẹ - ẹniti o ko sinu adanwo lati le yọ wura ti o mọ pọnrọngandan jade.

Niti paapa wọn wọ ọ lọ si ọdọ Mah'muun ni ẹniti wọ de e ni sẹkẹsẹkẹ, ti o si ti ṣe adehun iya ti o lekoko fun un siwaju ki o to de ọdọ rẹ, titi ti ọmọ-ọdọ Imaam Ahmad kan fi sọ pe:

Yio jẹ ohun ti yio wuwo fun mi irẹ baba Abdullah, pe Mahmuun ti bọ ida kan kuro ninu apo rẹ ti ko si bọ iru rẹ ri saaju eleyi, atipe dajudaju o ti bura pẹlu ijẹ alasunmọ rẹ si ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a –, wipe ti oo ba ti jẹ ipe oun lọ si ibi gbolohun wipe Al-Qurani ẹda Ọlọhun ni, oun yio pa ọ pẹlu ida naa.

Al-Bidaayatu wan-Nihaayah 1/332

Nibiyi ni awọn ọjọgbọn ilu Bas'roh ti lo anfaani yii lati wi awọn gbolohun idurosinsin fun asaaju wọn.

Ninu tira As'siyar ti alufa wa Al-Dha'abiy 11/238 lati ọdọ Abu Jah'far Al-An'baariy, o sọ pe:

Nigbati wọn gbe Ah'mad de ọdọ Mah'muun wọn fun mi ni iro, mo si sọda agbami Furootu, o si jẹ ẹniti o joko sinu ile kekere kan, mo wa salamọ si i, o si sọ pe: irẹ Abu Jah'far o ti daamu pupọ. Mo wa sọ fun un pe: irẹ eleyi, ori lo jẹ leni ti awọn eeyan si nwo ọ kose, mo si fi Ọlọhun ṣe ẹlẹri ti o ba le jẹ ẹ ni oo lọ sibi wipe Al-Qurani ẹda Ọlọhun ni, awọn eeyan naa a jẹ ipe o, ti oo ba wa jẹ ẹ ni oo, ọpọlọpọ ninu awọn eeyan ni yio kọ, pẹlu gbogbo eleyi naa ti ọkunrin naa o ba pa ọ, dajudaju wa pada ku ni, ko si ibuyẹ fun iku, yaa paya Ọlọhun ki o si ma jẹ ẹ ni oo. Ni Ah'mad ba bẹrẹ si ni sun ẹkun ti o si nsọ pe: maa sha Alloohu. Lẹyinna ni o wa sọ pe: irẹ Abu Jah'far tun un wi.. ni mo ba tun un wi fun un , o si nsọ pe: Maa sha Alloohu… ọrọ rẹ pari si ibiyi.

Imaam Ah'mad sọ nigbati o nṣe alaye irin ajo rẹ lọ si ọdọ Mah'muun.

A de aaye kan ti ilẹ rẹ fẹ ni aarin oru, ni wọn wa mu arakunrin kan wa ba wa o si sọ pe: ewo ninu yin ni Ah'mad ọmọ Hanbal. Wọn sọ fun un pe: eleyi ni. O wa sọ fun ẹni ti o ni rakunmi pe: ṣe pẹlẹpẹlẹ..lẹyinna ni o wa sọ pe: irẹ eleyi, kini yio da fun ọ ti wọn ba pa ọ si ibiyi, ti wa si wọ alujanna, lẹyinna ni o wa sọ pe: mo fi ọ le Ọlọhun lọwọ, ni o ba lọ. Mo si beere nipa rẹ, wọn sọ fun mi pe: o jẹ arakunrin kan ninu larubawa ninu iran Robiiha o nṣe awọn aṣọ ti wọn fi irun ẹran ṣe ni abule, wọn n pe e ni: Jaabir ọmọ Aamir ti wọn maa nsọ ọrọ rẹ ni daada

Siyaru Ah'laamin Nubalaah 11/241

Ninu tira Al-Bidaayatu wan-Nihaayah: dajudaju larubawa oko kan sọ fun Imaam Ah'mad pe:

Irẹ eleyi, iwọ ni asiwaju fun awọn eeyan, oo wa gbogbo jẹ aburu fun wọn, atipe dajudaju olori awọn eeyan ni ọ loni, oo si gbọdọ jẹ ipe wọn lọ sibi nkan ti wọn npe ẹ si, ti yio wa mu ki awọn naa jẹ wọn ni oo, ti wa fi wa lọ ru gbogbo ẹsẹ wọn ni ọjọ igbedide, atipe ti o ba nifẹ Ọlọhun, se suuru lori ohun ti o wa ninu rẹ; toripe dajudaju ohun ti n bẹ laarin rẹ ati alujanna ko ju ki wọn pa ọ lọ.

Imam Ah'mad sọ pe:

Ọrọ rẹ jẹ ohun ti o fun ipinu mi ni agbara lori ohun ti mo wa nibi kikọ kuro nibi nkan ti wọn pe mi si.

Al-Bidaayatu wan-Nihaayah 1/332

Ninu ẹgbawa kan: Imaam Ah'mad sọ pe:

Mi o gbọ ọrọ kankan ti o waye lori alamọri yi ti o ni agbara to ọrọ larubawa oko yii, eleyi ti o ba mi sọ ni aaye ti a npe ni RAH'BATU TAOQ “oun naa ni ilu kan ti o wa laarin Ar-Riqqoh ati Bagdaad ni eti Al-Furoot, o sọ pe: irẹ Ah'mad, ti ododo ba pa ọ, o ku iku shahiid (ẹniti o ku si oju ogun) niyẹn, atipe ti o ba si pada sẹmi, waa sẹmi ni ẹni ẹyin… o si fun ọkan mi ni agbara.

Siyaru Ah'laamin Nubalaah 11/241

Imam Ah'mad nsọ nipa ririnpọ pẹlu ọdọkunrin ti njẹ Muhammad ọmọ Nuuh eleyi ti o duro sinsin pẹlu rẹ nibi fitina na.

Mi o ri ẹnikan ti o fi n duro lori aṣẹ Ọlọhun to to Muhammad ọmọ Nuuh, toun ti bi o se kere ni ọjọ ori ti imọ rẹ o si to nkan, dajudaju mo nrankan ki o pari pẹlu daadaa. O sọ fun mi ni ọjọ kan pe: irẹ baba Abdullaah, Ọlọhun dọwọ rẹ Ọlọhun dọwọ rẹ, dajudaju oo da gẹgẹbi emi, o jẹ ẹniti awọn eeyan n wo kọṣe, awọn ẹda nnaga wo ọ, lati gbọ ohun ti yio ti ọdọ rẹ jade, wa paya Ọlọhun, wa duro sinsin lori aṣẹ Ọlọhun. O si ku, mo si kirun si i lara, mo si sin in.

Siyaru Ah'laamin Nubalaah 11/242

Titi ti o fi de ori awọn ara ọgba-ẹwọn ti Imaam Ah'mad maa nki irun fun ti wọn si ti de e, awọn naa kopa ninu fifi ẹsẹ rẹ rinlẹ.

Imaam Ah'mad sọ ri ninu ẹwọn pe:

Mi o bikita pẹlu atimọle yi – oun pẹlu ibugbe mi o yatọ si ara wọn – mi o si bẹru fifi ida pani, ohun ti mo nbẹru ni fitina ẹgba, ni ọkan ninu awọn ara ẹwọn ba gbọ o si sọ pe: ko si laburu fun ọ irẹ baba Abdullah, ko ju ẹgba meji naa lọ, lẹyinna oo nii mọ ibiti iyoku ba n bọ si, afi bi igbati wọn mu ibanujẹ kuro fun un.

Siyaru Ah'laamin Nubalaah 11/240

Wa se oju kokoro irẹ ọmọ-iya mi alapọnle wiwa isiti lọdọ awọn ẹniire: ki o si ronu si i nigbati wọn ba wi i fun ọ

Wa a ki o to ṣe irin ajo ti o ba npaya ohun ti o le ṣẹlẹ nibẹ.

Wa a ni igba adanwo, tabi siwaju ajalu ti o nlero.

Wa a ti wọn ba yan ọ si ipo kan tabi o jogun dukia kan pẹlu ọrọ

Wa fi ẹmi ara rẹ rinlẹ, ki o si fi ẹlomii naa rinlẹ, atipe Ọlọhun ni aayo awọn muumini.

Ẹlẹkẹẹdogun

Wiwoye si idẹra alujanna ati iya ina ati iranti iku.

Atipe alujanna ilu awọn idunu ni, ati ipẹtu si awọn ibanujẹ, ati ibusọ awọn muumini, atipe ẹmi ohun ti a da lori aile fi ara rẹ jin ati aile ṣiṣẹ ati aini idurosinsin ni, ayaafi pẹlu ki o ri ẹsan ti yio sọ awọn inira naa di irọrun fun un, ti yio si rọ awọn wahala ati inira oju ọna fun un.

Toripe ẹniti o ba ni imọ nipa ẹsan, wahala iṣẹ a rọrun fun un, ti yio si maa rin ti yio si mọ wipe ti ẹsẹ o ba ti mulẹ alujanna ti ibu rẹ ṣe deede sanmọ mejeeje ati ilẹ mejeeje a bọ mọ ọn lọwọ, lẹyinna dajudaju ẹmi ni bukaata si ohun ti yio gbe e kuro ninu ẹrọfọ ilẹ ti yio si fa a lọ si agbaye ti o ga.

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti o maa nlo iranti alujanna lati fi fi ẹsẹ awọn saabe rẹ rinlẹ.

Ninu hadiith ti o daa ti o si ni alaafia, ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – rekọja ni ọdọ Yaasir ati Ammaar ati Umu Ammaar ti wọn si nfi ara ni wọn nitori ti Ọlọhun ti O ga, o wa sọ fun wọn pe:

Suuru di ọwọ yin o ẹyin ara ile Yaasir, Suuru di ọwọ yin o ẹyin ara ile Yaasir; toripe alujanna ni adehun yin

Al-Haakim lo gba a wa 3/383

O si jẹ hadiith ti o daa ti o si ni alaafia, wo igbejade rẹ ninu tira Fiq'hus Siiroh eleyi ti alufa wa AL-Albaaniy se ifirinlẹ rẹ, oju-ewe 103

Bakanna o jẹ ẹniti maa nsọ fun awọn ansọọriy – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pe:

Dajudaju ẹẹ se alabapade imọtara-ẹni-nikan lẹyin mi o, ki ẹ yaa ṣe suuru titi ti ẹ o fi pade mi nibi Al-Hao'd (akeremọdo ti o jẹ ti Anabi).

Wọn fi ẹnu ko le e lori.

Bakanna ni pe ẹniti o ba woye si iṣesi ikọ meji ninu saare, ati ni ọjọ igbende, ati nibi iṣiro iṣẹ, ati nibi osuwọn, ati ni ori afara, ati awọn aaye to ku ni ọjọ ikẹhin.

Gẹgẹbi o ṣe jẹ wipe imaa ranti iku maa nsọ musulumi kuro nibi iparun, ti o si maa mu u duro nibi aala Ọlọhun ti ko si ni kọja rẹ.

Toripe dajudaju ti o ba ti mọ wipe dajudaju iku sunmọ ọn ju okun bata rẹ lọ, atipe asiko rẹ le ma ju ẹyin iṣẹju diẹ lọ, bawo wa ni ẹmi rẹ o ṣe wa jẹ ki o nifẹ si yiyẹgẹrẹ, tabi lati maa tẹsiwaju ninu iṣina.

Fun idi eyi, o sọ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pe:

Ẹ pọ lẹniti yio maa ṣe iranti ohun ti maa n wo ile adun.

Tirimithiy lo gba a wa 2/50, to o si so wipe o ni alaafia ninu tira Ir'waahul Galeel 3/145

Awọn aaye idurosinsin

O pọ gan-an o si ni bukaata si alaye, didarukọ diẹ ninu rẹ lakotan ti to wa ni aaye yi.

Alakọkọ

Didurosinsin nibi awọn fitina

Awọn iṣipopada ti maa nde ba awọn ọkan okunfa rẹ ni awọn fitina, ti awọn fitina idunnu ati ilekoko ba wa de ba ọkan, ko si ẹniti yio duro sinsin ayaafi awọn ti wọn ni amọdaju ti igbagbọ si ti fi ọkan wọn ṣe ibugbe.

Atipe ninu awọn oniranran fitina ni:

Fitina dukia

“Atipe o nbẹ ninu wọn ẹniti o ṣe adehun fun Ọlọhun wipe ti O ba fun wa ninu ọla Rẹ ao maa ṣe saara ao si maa bẹ ninu awọn ẹniire".

“Nigbati O wa fun wọn ninu ọla Rẹ wọn ṣe ahun pẹlu rẹ, wọn si pẹyinda lẹniti o gunri"

Suuratut-Taobah 75-76

Fitina ipo

“Fun ẹmi ara rẹ ni suuru pẹlu awọn ti wọn npe Ọlọhun ni owurọ ati ni aṣalẹ ti wọn n rankan ojurere Ọlọhun, oo si gbọdọ ṣi oju rẹ kuro lọdọ wọn lẹniti fi nwa yodoyindin ile-aye, oo si tun gbọdọ tele ẹniti a ti ṣi ọkan rẹ kuro nibi iranti wa ti o si tele ifẹnu rẹ ti gbogbo alamọri rẹ si jẹ aṣeju".

Suuratul Kah'f 28

O si tun sọ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – nipa aburu fitina mejeeji ti o saaju pe:

Ikooko meji ti ebi npa ti wọn wa tu wọn sile ni aarin agbo agutan ko lee ba agbo naa jẹ to bi ojukokoro ọmọniyan si dukai ati ipo ṣele ba ẹsin rẹ jẹ.

Imaamu Ah'mad lo gba a wa ninu tira Mus'nad 3/460, o si tun wa ninu tira Sohiihul Jaamih 5496.

Itumọ rẹ nipe dajudaju ojukokoro ọmọniyan lori dukia ati ipo le lati ba ẹsin jẹ ju ikooko meji ti wọn tu silẹ laarin agbo agutan lọ.

Fitina iyawo

“Dajudaju o nbẹ ninu awọn iyawo yin ati awọn ọmọ yin ẹniti o jẹ ọta fun yin, ki ẹ ya ṣọra fun wọn".

Suuratut-Tagoobun 14

Fitina awọn ọmọ

Ọmọ nkan ti maa sọ ni di ojo ni, ti si maa n sọ ni di ahun, ti si maa n ba ni ninu jẹ

Abu Yah'la lo gba a wa 2/305 ti o si tun ni awọn ẹgbawa mii ti nṣe ẹri rẹ, atipe o wa ninu Sohiihul Jaamih 7037

Fitina ilo-agbara-leni-lori ati ijẹgaba-lori-ẹni ati iṣe-abosi-ẹni: apẹrẹ to daa ju fun un ni gbolohun Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn ti o sọ pe:

“A ṣebi le awọn ti wọn gbẹ koto"

“Ina ti wọn nko"

“Nigbati wọn joko si eti rẹ"

“Atipe wọn si tun jẹri si ohun ti wọn nṣe fun awọn onigbagbo ododo".

Wọn o si fi iya jẹ wọn nitori nkankan tayọ wipe wọn ni igbagbọ si Ọlọhun Ọba Abiyi Ọba Ẹlẹyin.

Ọba ti o jẹ wipe ti Ẹ ni ikapani sanmọ ati ilẹ, ti O si jẹ Ẹlẹri lori gbogbo nkan.

Suuratul Buruuj 4-9

Atipe Bukhaari gba a wa lati ọdọ Khabbaab – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe:

A ke gbajari lọ ba ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – o si jẹ ẹniti o fi aṣọ nla kan rọ ori ni abẹ booji Kah'bah

O wa sọ - ki ọla maa jẹ ti ẹ - pe:

Ninu nkan ti o ti ṣẹlẹ siwaju yin nipe, wọn o mu ẹnikan wọn o si gbẹ ilẹ fun un, wọn o si ju u si inu rẹ wọn o si tun mu ọbẹ irẹ-igi wa, wọn o si gbe e si i ni ori, wọn o si ge e si meji ogbọọgba, wọn yio si tun fi awọn iyarun onirin ya ẹran rẹ ati eegun rẹ lọtọọtọ, ti gbogbo iyẹn o si ni ṣẹri rẹ kuro nibi ẹsin rẹ

Bukhaari lo gba a wa, wo inu tira Fat'hul Baari 12/315

Fitina Dajjaal

Oun si ni fitina iṣẹmi aye ti o tobi ju

Mo pe ẹyin eeyan, dajudaju koi tii si fitina Kankan ni orilẹ lati igbati Ọlọhun ti da Aadam ti o tobi to fitina Dajjaal.. ẹyin ẹrusin Ọlọhun, ẹyin eeyan: ki ẹ ya fi ara balẹ toripe maa royin rẹ fun yin ni iroyin ti Anabi Kankan o royin rẹ bẹẹ saaju mi.

Ibnu Maajah ni o gba a wa 2/1359, wo sohiihul Jaamih 7752.

Atipe Anabi sọ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – nipa awọn ipele idurosinsin awọn ọkan ati iyẹgẹrẹ rẹ.

Awọn fitina maa de ba awọn ọkan gẹgẹbi ẹni ni igi kọọkan, eyikeyi ọkan ti o ba wa gba a ti o si gbe e mu yio kan ekikan dudu kan si i, eyikeyi ọkan ti o ba si kọ ọ yio kan ekikan funfun kan si i, titi yio fi wa lori ọkan meji, lori ọkan funfun ti o dabi nkan ti o mọ kanga ko si le ko inira ba a lopin igbati awọn sanmọ ati ilẹ mejeeje ba si wa, ikeji ni dudu ti o ti ropọ mo funfun balahu ti o da gẹgẹbi ife omi ti o tẹ, ti ko nii da nkan daadaa mọ, ti ko si nii le kọ ibajẹ, ayafi ohun ti o ti kun ọkan rẹ ninu ifẹnu rẹ.

Imaam Ahmad gba a wa 5/386, ati Muslim 1/128, atipe gbolohun yi ti ẹ ni

Itumọ Ar'dul Asiir nipe: awọn fitina maa nlapa ninu ọkan gẹgẹbi ẹni ṣe maa nlapa ni ẹgbẹ ẹniti o ba sun si i lori

Itumọ Mur'baaddan nipe: funfun balawu ti dudu ti ropọ mọ ọn, itumọ Muja'khiyan nipe: ohun ti wọn ti da oju ẹ de ti wọn ti yi i pada

Eleekeji

Idurosinsin nibi ijagun si oju ọna Ọlọhun

“Mo pe ẹyin ti ẹ gba Ọlọhun gbọ ti ẹ ba ti pade awọn ikọ kan ki ẹ ya durosinsin".

Suuratul Anfaal 45

Atipe ninu awọn ẹṣẹ nla ninu ẹsin wa ni ki eeyan o sa kuro loju ogun, o jẹ ẹniti nwi lawitunwi – ki ikẹ ati ọla maa ba a – pẹlu awọn muumini ni oju ogun Khandaq ti oun naa si gbe erupẹ si ẹyin rẹ pe:

Fi ẹsẹ wa rinlẹ nigbati a ba ṣe alabapade awọn ọta.

Bukhaari lo gba a wa ninu iwe Al'gazawaat, ojupọnna Gaz'watul Khandaq. Wo Al-fat'hu 7/399.

Ẹlẹẹkẹta

Idurosinsin lori ilana to tọ

“O nbẹ ninu awọn muumini awọn ti wọn mu adehun ti wọn ba Ọlọhun ṣe ṣe, o si nbẹ ninu wọn ẹniti o ṣe alabapade iku rẹ, o si nbẹ ninu wọn ẹniti o nreti ki oun na o pade iku rẹ, wọn ko si yi adehun ti wọn ṣe pada"

Suuratul Ah'zaab 23

Awọn ipilẹ wọn kun wọn loju ju awọn ẹmi wọn lọ, ipinnu kan ni ti ko le yi pada.

Ẹlẹẹkẹrin

Idurosinsin ni asiko iku

Ẹẹ ri awọn keferi ati awọn onibajẹ, dajudaju wọn o nii le durosinsin ni awọn asiko ti wahala rẹ le, ko wa ni jẹ ki wọn ni ikapa lati pe gbolohun (laa ilaha illalloohu) nigbati wọn ba fẹ ku.

Ti eleyi si wa ninu awọn ami igbẹyin aburu gẹgẹbi wọn ṣe sọ fun arakunrin kan nigbati o fẹ ku.

Wi gbolohun (laa ilaaha illallaah) ni o ba bẹrẹ si ni nmi ori rẹ si ọtun ati osi lẹniti nkọ lati wi i.

Ẹlomii a tun maa sọ nigbati o ba fẹ ku pe:

Eleyi ni egige ti o daa, eleyi dinwo ni rira.

Ti ẹlẹẹkẹta o si maa ranti awọn orukọ egige ayo

Ti ẹlẹẹkẹrin o si maa kọ orin, tabi ki o maa ranti ololufẹ

Iyẹn nipe irufẹ awọn alamọri yi lo ko airoju ba wọn kuro nibi iranti Ọlọhun

Atipe wọn le ri lara awọn ẹni yii didudu oju wọn tabi bibajẹ oorun wọn, tabi yiyi kuro nibi idajukọ awọn musulumi nigbati ẹmi ba fẹ bọ ni ara wọn, atipe ko si ete kan ko si si agbara kan ayaafi pẹlu Ọlọhun.

Amọ awọn ẹniire ati ilana Anabi, dajudaju Ọlọhun maa nfi wọn ṣe kongẹ idurosinsin nigbati wọn ba fẹ ku, ti wọn o si ri gbolohun ijẹri mejeeji pe.

Atipe wọn le ri lara awọn wọnyi kikọ mọnamọna iwaju, wọn tabi didun oorun ara wọn, ati itujuka ati idunnu nigbati ẹmi ba fẹ bọ lara wọn.

Eleyi jẹ apẹrẹ ọkan lara awọn ti Ọlọhun fi ṣe kongẹ idurosinsin nigbati o fẹ ku, ẹni naa ni Abu Zur'ah Ar'rooziy, ọkan lara awọn agba alufa aladiisi, eleyi ni bi itan rẹ ṣe lọ:

Abu Jah'far Muhammad ọmọ Aliyy olukọ nkan Abu Zur'ah sọ pe:

A gbe Abu Zur'ah wa si Maashah'raan, abuleko kan ninu awọn abuleko Royyi ti o si jẹ ẹniti npọka iku lọwọ, ti Abu Haatim ati Ibnu Waarih ati AL'Mun'dhir ọmọ Shaazaan ati awọn mii yatọ si wọn si wa pẹlu rẹ.

Ni wọn ba sọ nipa hadith imaa nu ẹniti npọ iku ni gbolohun ijẹẹri ti o sọ pe:

Ẹ maa nu awọn oku yin ni gbolohun Laa ilaaha illal'loohu

Wọn si ntiju lati nu Abu Zur'ah ni gbolohun naa, ni wọn wa sọ pe ẹ wa ki a darukọ hadith na

Ni Ibnu Waarih wa sọ pe:

Abu Aasim ba wa sọrọ, Abdul hameed ọmọ Jah'far ọmọ Sooliu ba wa sọrọ, o si nsọ pe Ibnu Abi – ko si tayọ rẹ

Ni Abu Aatim wa sọ pe:

Bundaar ba wa sọrọ, Abu Aasim ba wa sọrọ, lati ọdọ Abdul hameed ọmọ Jah'far, lati ọdọ Sooliu, ko si tayọ rẹ, ti awọn yoku si dakẹ

Abu Zur'ah wa sọ, ti o si jẹ ẹniti npọka iku lọwọ ti o si si oju rẹ mejeeji, pe:

Bundaar bawa sọrọ, Abu Aasim bawa sọrọ, Abdul hameed bawa sọrọ lati ọdọ Sooliu ọmọ Abi Gareeb lati ọdọ Kathiir ọmọ Murroh lati ọdọ Muaadh ọmọ Jabal, o sọ pe:

Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:

Ẹniti igbẹyin gbolohun rẹ ba jẹ (laa ilaha illalloohu) yio wọ alujanna

Ni ẹmi rẹ ba jade ki Ọlọhun kẹ ẹ

Siyaru Ah'laamun Nubalaahu 13/76-85

Atipe Ọlọhun sọ nipa irufẹ awọn wọnyi pe:

"Dajudaju awọn ti wọn sọ wipe Alloohu ni Ọba wa ti wọn si duro deede, awọn malaika a maa sọkalẹ ti wọn ni igbati ẹmi ba fẹ jade lara wọn ti wọn o si maa sọ pe, ẹ ma bẹru ẹ si ma ba inu jẹ, ki ẹ si maa dunnu pẹlu alujanna ti wọn ti pese silẹ fun yin"

Suuratu Fussilat 30

Irẹ Ọlọhun ka awa naa kun wọn

Irẹ Ọlọhun a ntọrọ lọwọ Rẹ idurosinsin lori aṣẹ Rẹ ati ini-ipinnu lori itọsọna.

Atipe igbẹyin ipepe wa naa ni pe ọpẹ ni fun Ọlọhun Ọba gbogbo agbaye