Ibanisọrọ yii sọ daradara ti o yẹ ki o maa ti ọwọ musulumi kan jade si ọdọ musulumi keji ati awọn aburu ti o yẹ ki wọn maa le jina si ara wọn.
Awọn Ojuse Musulumi si ara wọn - (Èdè Yorùbá)
Ọla ti nbẹ fun kika Alukurani Alapọnle - (Èdè Yorùbá)
Idanilẹkọ yi sọ nipa ohun ti a npe ni Alukuraani pẹlu awọn ẹri lati inu ayọka rẹ, ọrọ si tun waye lori awọn ọla ti o wa fun kika rẹ ati awọn ẹkọ ti o rọ mọ kike rẹ.
Ajọse ti ọmọ Iya ninu Ẹsin Islam - (Èdè Yorùbá)
Idanilẹkọ yii da lori awọn koko mẹta wọnyii: (i) Pataki asepọ jijẹ ọmọ iya ninu ẹsin. (ii) Ẹsan ti o wa fun asepọ ọmọ iya ninu ẹsin. (iii) Awọn nkan ti o maa nba jijẹ ọmọ iya ninu ẹsin jẹ.
Anfaani yiyọ Saka (Zakat) fun Ẹnikọọkan ati fun Awujọ - (Èdè Yorùbá)
Alaye nipa ipo Saka yiyọ ninu ẹsin Islam ati awọn anfaani ti o wa nibi yiyọ rẹ yala ni abala ẹsin ni tabi abala iwa.
Awọn Isẹ ti Ẹsan wọn yoo sẹku fun Musulumi lẹyin Iku - (Èdè Yorùbá)
Idanilẹkọ yii da lori awọn Isẹ ti ẹsan wọn maa nbe gbere lẹyin iku pẹlu apejuwe lati inu ẹgbawa hadisi.
Ninu Awọn Ẹkọ Irinajo - (Èdè Yorùbá)
1- Ninu abala yi ọrọ waye lori awọn nkan ti o ye ki arinrinajo se ki o to bẹrẹ irinajo rẹ. 2- Ninu abala yi ọrọ waye lẹkunrẹrẹ lori awọn ẹkọ ti o yẹ ki arinrinajo maa mu lo ni asiko ti ba nse irinajo rẹ.
Ẹkọ nipa Apejẹ igbeyawo (Walimatu-Nikah) - (Èdè Yorùbá)
Idanilẹkọ yi sọ nipa idajọ ki eniyan se ounjẹ lati fi ko awọn eniyan lẹnu jọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu awọn ẹkọ ti o rọ mọ apejẹ sibi igbeyawo (walimọtu- nikahi).
Awọn Ẹko ti o rọ mọ Ọmọ-ọdọ tabi Osisẹ ti a gba si isẹ - (Èdè Yorùbá)
Alaye ni ẹkunrẹrẹ waye ninu idanilẹkọ yii lori ẹkọ ti o rọ mọ gbogbo ẹni ti n se isẹ sin eniyan.
Gba-fi-pamọ (Amaanah) Itumọ rẹ ati ohun ti o ko sinu - (Èdè Yorùbá)
Alaye ohun ti o njẹ gba-fi-pamọ lati inu Alukuraani ati Sunnah ati alaye gbogbo ohun ti o ko si abẹ gbafipamọ.
Awọn Iwọ Jijẹ Ọmọ-iya ninu Ẹsin Islam - (Èdè Yorùbá)
Akori kutuba yii da lori pataki ati iwọ ijẹ ọmọ iya ninu ẹsin Islam.
Awọn Ẹkọ ti o nbẹ fun jijẹ ati mimu - (Èdè Yorùbá)
1- Ninu abala yi ọrọ waye lori wipe ounjẹ ti Ọlọhun Allah pese fun wa idẹra ni o jẹ ati alaye idi ti o fi jẹ idẹra. Bakannaa awọn nkan ti o dara pupọ lati se akiyesi rẹ nigba ti a ba fẹ jẹ ounjẹ. 2- Abala yii jẹ itẹsiwaju....
Adua ati Asikiri - (Èdè Yorùbá)
1- Itumọ adua ati asikiri lati inu agbọye Alukuraani ati Sunnah pẹlu alaye lori ẹkọ adua ati asikiri ni sise. 2- Pataki adua, asiko gbigba adua ati gbogbo ohun ti o takọ ilana gbigbaa adua ni sise.

API

