×
Image

Itoju Awon Arun ni Ilana Islam - (Èdè Yorùbá)

Waasi yi so nipa awon ona iwosan ninu Islam. Oniwaasi so wipe awon aisan ti o maa nse awon eniyan pin si meji: aisan emin ati aisan ara. O si so wipe iso ti o dara julo nibi gbogbo arun naa ni iberu Olohun ati gbigbe ara le E. Lehinnaa,....

Image

Ojuse Odo Lori Atunse Awujo - 1 - (Èdè Yorùbá)

Olubanisoro se alaye wipe imo nipa Olohun Allah ni eniyan maa fi n mo iyato laarin ohun ti o dara ati eyi ti ko dara, o si so wipe eniti o ba mo ohun ti o dara yato si eyi ti ko dara ni yoo le gbero ayipada ni awujo.

Image

Ojuse Odo Lori Atunse Awujo - 2 - (Èdè Yorùbá)

Oniwaasi se afihan re wipe iyipada ko le waye laisi awon nkan wonyi: Alakoko: Agboye imo ijinle nipa esin Islam. Eleekeji: Wiwa awon imo ijinle ti awujo ni bukaata si. Eleeketa: Sise igbiyanju lati fi imo naa kede esin Islam.

Image

OWO- ELE (RIBA) - (Èdè Yorùbá)

Oniwaasi se alaye itumo aaya (276) ninu Suuratu Bakora, o si so ni ekunrere awon aburu ti o wa nibi ki eniyan maa gba owo ele.

Image

Ojuse ati Eto Awon ti Oku fi Sile - (Èdè Yorùbá)

Oniwaasi so nipa awon eto ti Islam la kale fun awon ti oku fi sile, gege bii baba, iya, oko, iyawo, omokunrin, omobinrin ati beebeelo. O si tun menu ba awon asise ti o maa nwaye lori awon eto wonyi.

Image

Ojuse Imam ninu Islam - 1 - (Èdè Yorùbá)

Ibanisoro ti o so nipa awon majemu ti o gbodo pe si ara eni ti yoo ba wa ni ipo Imaam, yala Imaam ti inu irun ni tabi Imaam ti yoo je olori fun gbogbo Musulumi.

Image

Ojuse Imam ninu Islam - 2 - (Èdè Yorùbá)

Apa keji ibanisoro naa, olubanisoro menu ba idajo wiwo masalaasi, alaye bi onirin-ajo yoo se maa ki irun re leyin onile ati idakeji, bakannaa idajo gbigba iwaju irun koja.

Image

Ojuse Imam ninu Islam - 3 - (Èdè Yorùbá)

Apa keta ibanisoro naa so nipa idajo kiko masalaasi, bakannaa ni oro waye lori ohun ti o leto ki a se ninu mosalaasi ati awon ohun ti ko leto, leyinnaa ni idahun waye si awon ibeere.

Image

Esin Islam ni Ile Africa laarin Shariah ati Asa - (Èdè Yorùbá)

Ibanisoro yi da lori awon asa ti Islam fi ara mo ati awon eyi ti ko fi ara mo ni odo awon eya Yoruba ati die ninu awon eya miran ni ile alawo dudu (Africa). Awon olubanisoro mejeeji si mu awon apeere asa naa wa, bakannaa ni won menu ba....

Image

IRIN AJO TI KO SE YE (IRIN AJO IKU) - (Èdè Yorùbá)

Oro nipa iku ati bi a se n we oku ni ilana esin Islam, pelu itoka si die ninu awon ohun ti o je dandan ki Musulumi ni igbagbo si lehin iku.

Image

Idajo Sise Ise Ode ninu Islam - 1 - (Èdè Yorùbá)

Oro ni soki nipa ise ode ninu Islam, olubanisoro bere oro re pelu alaye bi esin Islam se dasi gbogbo igbesi aye omo eniyan ati awon eda miran ti ko si fi ibikankan sile lai dasi.

Image

Idajo Sise Ise Ode ninu Islam - 2 - (Èdè Yorùbá)

Ninu apa yi: (1) Oro nipa awon irinse ti eniyan fi le se ode. (2) Oro nipa awon eranko ti ko leto ki Musulumi je. (3) Die ninu awon eko sise ise ode.