×
Idajọ fifi iya jẹ ọmọ akẹkọ l’obinrin pẹlu lilu u ni ẹgba, ti o si jẹ wipe o rọrun lati se itọsọna fun un pẹlu ọrọ ẹnu.

    Idajọ Nina Ọmọ

    Akẹkọ L’obinrin

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Oju ewe ayelujara

    IBEERE ATI IDAHUN NIPA ỌRỌ ẸSIN ISLAM

    Labẹ Amojuto:

    Sheikh Muhammad Sọọlih Al-munajjid

    Itumọ si ede Yoruba: Rafiu Adisa Bello

    Atunyẹwo : Hamid Yusuf

    2015 - 1436

    حكم ضرب الطالبات

    « بلغة اليوربا »

    موقع الإسلام سؤال وجواب

    الشيخ محمد صالح المنجد

    ترجمة: رفيع أديسا بلو

    مراجعة: حامد يوسف

    2015 - 1436

    IBEERE ATI IDAHUN NIPA ỌRỌ ẸSIN ISLAM

    FATWA: [118683]

    IBEERE:

    Kinni idajọ fifi iya jẹ ọmọ akẹkọ l’obinrin pẹlu lilu u ni ẹgba, ti o si jẹ wipe o rọrun lati se itọsọna fun un pẹlu ọrọ ẹnu?

    …………………………………………………..…………………………..

    IDAHUN:

    Ọpẹ ni fun Ọlọhun.

    Ẹsin Islam pepe lọ si ibi ki olukọ maa se pẹlẹpẹlẹ nigbati o ba n kọ awọn ọmọde ati agbalagba ni ẹkọ, sugbọn ti bukaata ba pepe lọ si ibi ibawi pẹlu lilo ẹgba, ko si aburu nibẹ.

    Ninu isesi awọn omugọ eniyan ni ki wọn ma fun ẹniti wọn n ba se ni apọnle ati ọwọ, eyi ti o le jẹ ki ẹni naa lo agbara lati se atunse awọn isesi ti ko dara to.

    Eleyi ni ọrọ Sheikh Abdur-rahman bin Jibrin, ninu tira [Fatawa 'Ulamaa- il- baladil haraam, oju ewe: 399].

    Ọlọhun ni Onimimọ julọ.