Ilu lilu nibi inawo tabi ajoyọ ko ba Ẹsin Islam mu
Àwọn ìsọ̀rí
Àwọn ipilẹ ti a ti mú nǹkan
Full Description
Ilu lilu nibi inawo tabi ajoyọ ko ba Ẹsin Islam mu
[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]
Oju Ewe Ayelujara
IBEERE ATI IDAHUN NIPA ỌRỌ ẸSIN ISLAM
Labẹ Amojuto:
Sheikh Muhammad Sọọlih Al-munajjid
Itumọ si ede Yoruba: Rafiu Adisa Bello
Atunyẹwo : Hamid Yusuf
2015 - 1436
الطبول في المناسبات منكر
« بلغة اليوربا »
موقع الإسلام سؤال وجواب
الشيخ محمد صالح المنجد
ترجمة: رفيع أديسا بلو
مراجعة: حامد يوسف
2015 - 1436
IBEERE ATI IDAHUN LORI ỌRỌ ẸSIN ISLAM
FATWA: [12929]
IBEERE:
Kinni idajọ lilọ si ibi apejẹ tabi ajọyọ, ti awọn nkan ti ko ba ẹsin Islam mu gẹgẹ bii lilu ilu wa nibẹ, ti o si jẹ wipe ẹniti o pepe si apejẹ naa jẹ ọkan ninu awọn alasunmọ ẹni, ti awọn nkan ti ko ba ẹsin mu yi si wa nibẹ?
…………………………………………………………………
IDAHUN:
Ọpẹ ni fun Ọlọhun.
Ko lẹtọ lati jẹ ipe fun iru ajọyọ bayi pẹlu awọn nkan ti o lodi si ẹsin Islam ti o wa nibẹ. Bakannaa, ti wọn ba n mu ọti tabi siga nibẹ, tabi wọn n wo fiimu ti sise afihan ihooho ara wa nibẹ, tabi awọn ọkunrin ati obinrin ti wọn kii se ẹlẹtọ ara wọn n wa papọ nibẹ, tabi awọn obinrin n fi ẹwa ara wọn han sita nibẹ.
Sugbọn ti o ba jẹ wipe lilọ sibẹ rẹ le jẹ okunfa ayipada awọn nkan naa tabi ki o dinku, tabi o jẹ wipe ti o ba lọ si ibẹ, awọn ti wọn n se awọn aburu naa yoo se apọnle rẹ, ti wọn yoo si fi awọn nkan naa silẹ, nigba naa o le lọ sibẹ. Sugbọn ti o ba jẹ wipe lilọ sibẹ rẹ ko le mu ayipada ba awọn iwa abuku naa, ko lẹtọ fun ọ lati lọ rara, koda ki o jẹ alasunmọ rẹ ni ẹni ti o pepe si apejẹ naa.