×
Idajọ ki Musulumi maa lo oruka ti wọn fi fadaka se pẹlu adisọkan ti ko dara.

    Lilo Oruka Fadaka ninu Osu Rajab

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Oju Ewe Ayelujara

    IBEERE ATI IDAHUN NIPA ỌRỌ ẸSIN ISLAM

    Labẹ Amojuto:

    Sheikh Muhammad Sọọlih Al-munajjid

    Itumọ si ede Yoruba: Rafiu Adisa Bello

    Atunyẹwo : Hamid Yusuf

    2015 - 1436

    لبس خواتيم الفضة في شهر رجب

    « بلغة اليوربا »

    موقع الإسلام سؤال وجواب

    الشيخ محمد صالح المنجد

    ترجمة: رفيع أديسا بلو

    مراجعة: حامد يوسف

    2015 - 1436

    Lilo Oruka Fadaka ninu Osu Rajab

    Fatwa: [114424]

    Ibeere:

    Ninu ẹbi wa, wọn fun wa ni oruka fadaka (silver) ti wọn kọ awọn nkankan si lara pẹlu ede Larubawa, ti wọn si se oruka naa ninu osu Rajab. Ibeere mi ni wipe: mo fẹ mọ boya lilo irufẹ oruka bayi wa ni ibamu pẹlu Shẹria Islam tabi o lodi si i.

    Idahun:

    Ọpẹ ni fun Ọlọhun.

    O lẹtọ fun ọkunrin lati lo oruka ti wọn fi fadaka se, gẹgẹ bi o se lẹtọ fun obinrin naa.

    Ninu hadiisi ti Bukhari ati Muslim gba wa lati ọdọ Anas [ki Ọlọhun yọnu si i], o sọ wipe: “Ojisẹ Ọlọhun kọ iwe kan tabi o fẹ kọ iwe kan, wọn wa sọ fun un wipe: Awọn iran miran kii ka iwe ti ko ba ni ontẹ lara, ojisẹ Ọlọhun wa ni ki wọn se oruka fun oun, wọn si kọ Muhammadu Rọsuulu-llahi si ara rẹ, o da gẹgẹ bii pe mo n wo oruka funfun naa bayi ni ọwọ rẹ”.

    Alfa ẹsin An-nawawi [ki Ọlọhun kẹ ẹ] sọ wipe: “O lẹtọ fun obinrin ti o ti ni ọkọ ati eyi ti ko tii ni ọkọ lati lo oruka ti wọn se pẹlu fadaka, gẹgẹ bi o se lẹtọ fun un lati lo oruka ti wọn fi wura (Goolu) se, awọn onimimọ fi ẹnu ko lori eleyi, ko si si iyapa kankan lori rẹ. Alfa ẹsin Al-khataabi sọ wipe: Wọn korira ki o lo oruka fadaka nitoripe awọn okunrin ni wọn maa n lo o. O tun sọ wipe: Ti obinrin ko ba ri oruka ti wọn fi wura (Goolu) se, ki o fi nkankan kun oruka fadaka ki awọ rẹ le yipada diẹ, ọrọ yi ko si fi ẹsẹ rinlẹ. Eyiti o fi ẹsẹ rinlẹ ni wipe o lẹtọ ki obinrin lo oruka fadaka”. Lẹhinnaa o tun sọ wipe: “O lẹtọ fun okunrin lati lo oruka fadaka, yala ẹniti o jẹ alasẹ tabi ẹlomiran, awọn onimimọ si fi ẹnu ko lori eleyi. Sugbọn ọrọ ti o wa lati ọdọ apakan ninu awọn onimimọ ni ilu Shaamu wipe ko lẹtọ ki okunrin lo oruka fadaka ti kii baa se alasẹ, eleyi ko fi ẹsẹ mulẹ, ko si ni ẹri kankan rara, o si yapa si ohun ti awọn asiwaju ninu ẹsin fi ẹnu ko le lori. Onimimọ kan ti orukọ rẹ n jẹ Al-‘abdari ati awọn miran ti fi idi rẹ mulẹ wipe ẹnu ko lee lori”.

    Ni afikun, o lẹtọ lati tẹ nkan tabi kọ nkan si ara oruka, sugbọn sise adayanri osu Rajab fun awọn nkan wọnyi ko si ipilẹ fun un. Fun idi eyi, ẹniti o ba lo oruka kan ninu osu Rajab pẹlu adisọkan wipe o n fi n wa asunmọ si ọdọ Ọlọhun tabi wipe lilo oruka naa ninu osu Rajab ni ọla kan, irufẹ ẹni bẹẹ ti se asise, o si ti se adadasilẹ ninu ẹsin.

    Nitorinaa, ki gbogbo Musulumi sọra lati maa kọ nkan si ara oruka pẹlu ero wipe o le se okunfa oore tabi ki o ti aburu awọn alujọọnu ati awọn ajẹ ati awọn onikeeta danu.

    Koko ọrọ ni wipe: Lilo oruka ati kikọ nkan si ara rẹ ko si eewọ kankan nibẹ, ohun ti o jẹ eewọ ni lilo o pẹlu adisọkan wipe o le se okunfa asunmọ si ọdọ Ọlọhun tabi sisa asiko kan ni ẹsa lati lo o, tabi wiwa alubarika pẹlu rẹ tabi mimu u ni ohun ti o le se anfaani kan fun eniyan lẹyin Ọlọhun.

    Ọlọhun ni O ni imọ julọ.