NJE A LE RI ANABI NI OJU ALA?
Àwọn ìsọ̀rí
- Àwọn àlá << Àwọn ẹ̀kọ́ << Awọn iwa rere
- Àwọn ẹ̀kọ́ << Awọn iwa rere
- Àwọn ọrọ oríṣiríṣi ti o jẹ mọ́ Anọbi Islam << Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni << Ìgbàgbọ́ nínú àwọn ojiṣẹ àti àwọn ìròyìn wọn << Ìgbàgbọ́ ati awọn origun rẹ̀ << Ìmọ̀ Akiida
- Awọn ìwà ati ìròyìn Anabi << Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni << Ìgbàgbọ́ nínú àwọn ojiṣẹ àti àwọn ìròyìn wọn << Ìgbàgbọ́ ati awọn origun rẹ̀ << Ìmọ̀ Akiida
Àwọn ipilẹ ti a ti mú nǹkan
Full Description
NJE A LE RI ANABI MUHAMMAD NI OJU ALA
[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]
Ishaaq bn Ahmad al Ilaalawi
Atunyewo: Rafiu Adisa Bello
2013 - 1434
رؤية النبي ﷺ في المنام
« بلغة اليوربا »
إسحاق بن أحمد الإلالوي
مراجعة: رفيع أديسا بلو
2013 - 1434
NJE A LE RI ANABI MUHAMMAD NI OJU ALA?
Ni otito, eniyan le ri anabi Muhammad-alaafia Olohun fun un - ni oju oorun. Sugbon Shatani le pe ara re ni anabi gege bi ero okan wa se le yipada si ohunkohun nigbati a ba ti sun. Nipase bee, riri anabi loju oorun lee je iro idunnu, o lee je alakala lati owo esu, o si lee je abayori ife okan wa.
Ronu si awon ala yii:
Akoko: Onimo hadiisi agba, Bukhaari - aanu Olohun fun un, nigbati o wa ni kekere o lala pe oun nfi abebe le esinsin kuro ni oju anabi[1] - alaafia Olohun fun un.
Ikeji: Enikan so pe oun ri anabi loju oorun ti o we lawani funfun laini irugbon, o si so bayi pe: baba agba ni mo je fun o, eje mi si ni iwo nse; nitorinaa, asegbe ni ohunkohun ti o ba se, mo si ti fun o ni ase ‘wi bee je bee’.
Iketa: Muhammad Al- Buusoyri[2] so pe: Nigbati arun ‘ro lapa ro lese’ mu mi, ti ko si gbo itoju, mo ko orin eyin anabi ti opa orin naa to ogun mejo (160) ni oju oorun mi, mo ri anabi Muhammad, o fi owo pa owo ati ese mi o si wi fun mi pe ki n ko orin eyin naa. Anabi fi idunnu re han si mi nigbati o gbo orin eyin naa. Nigbati mo dide ni ori oorun naa, mo gbe apa o see gbe, mo si gbe ese naa ni irorun[3].
Opa orin kan ninu iwe orin Buusoyri lo bayii pe:
فإن من جودك الدنيا وضرتها # ومن علومك علم اللوح والقلم
Itumo: O daju pe ninu owo ore ire Anabi ni aye ati orun # o si daju pe ninu imo re ni imo patako ti Olohun ko kadara si ati gege ikowe ti Olohun fi ko o.
Ela loro, ala idunnu ni apejuwe akoko, alakala lati owo esu ni apejuwe ikeji; nitoripe ko si asegbe fun enikan laye yii. Ala okan lasan si ni eleketa. Idi abajo nipe Olohun ni O se eda aye ati orun kii se Anabi, bee si ni ikapa lori kadara je ti Olohun nikan soso. Anabi Muhammad ko ni imo ikoko kan yato si eyi ti Olohun ba fi mo o. Olohun so pe: “[OLOHUN] ONI IMO OHUN TI O PAMO; NITORINAA KII SE AFIHAN IMO IKOKO RE FUN ENIKANKAN. AYAAFI EYI TI O BA WU ﷻ FUN OJISE TI O SALESA.”[4]
KINI AMI TI A O FI MO ANABI ODODO LOJU OORUN?
Otito ni oro Anabi Muhammad- alaafia Olohun fun un- ti o so pe:
من رآني فقد رآني فإن الشيطان لا يتمثل بي
Itumo: “ENI TI O BA RI MI LOJU ALA, O TI DAJU PE EMI GAN-AN NI O RI; TORIPE, ESU [SHATANI] KO LE GBE AWORAN MI WO”[5].
Eniyan ti ko ba Anabi laye, bawo ni o se fe mo aworan re yato si aworan elomiran? Ni idahun si ibeere yii, awon onimimo pin si ona meta:
IDAHUN AKOKO: Ibnu Siiriin, Baaqilaani ati Ibnu Taymiyya so pe: Ki a to le gba pe eniyan ri Anabi loju oorun, ni otito, o gbodo so irisi re, irisi naa si gbodo wa ni ibamu si akosile awon omoleyin ojise-nla - alaafia Olohun fun un.
IDAHUN KEJI: Al Maaziri ati Nawawi gba pe eniyan lee lala ri Anabi Muhammad- alaafia Olohun fun un- ni irisi ala aditu tabi ni irisi ala ologeere. Awon onimo mejeji naa si panupo pe bi ala naa ba je ologeere, o gbodo ni ibamu si irisi Anabi Muhammad ninu akosile awon onimimo.
IDAHUN KETA: Adajo agba, Abu bakr so pe: Bi eniyan ba ri Anabi Muhammad- alaafia Olohun fun un - ni irisi ti o ni akosile, o daju pe Anabi gan-an ni o ri. Sugbon bi o ba ri i ni irisi miran, o daju pe apeere ojise-nla ni eniyan naa ri.
KINNI ANFAANI RIRI ANABI NI OJU ALA?
Itutu oju ati iro idunnu ni fun eniti o ba ri Anabi loju oorun. O si ye ki a mo amodaju pe ilana ijosin ko lee dinku tabi lekun nipase riri Anabi loju ala. Bakannaa ni ko rorun ki enikan gba asalatu tuntun tabi adua ni oju oorun. Eniyan ti o ba la iru ala yii ti la ala okan tabi alakala ti o n waye lati odo Esu [Shatani].
Fun akotun iwadi, wo kitaabut-ta’biir ninu Fathul Baari ati kitaabur-ru’yaa ninu sohiihu Muslim bisharhin Nawawi.
[1] Fathul Baari, Muqoddimah lati owo Ibnu Hajar.
[2] Oruko re ni Muhammad bn Sa’eed. A bii ni igberiko kan ni ilu Egypt ni odun 608 leyin hijrah osi ku ni odun 659 leyin hijrah.
[3] Haashiyatul Baajuuri, Iwe Ibraahiim Al Baajuuri, oju ewe keji.
[4] Suuratul Jin, Aayah 26 - 27
[5] Sohiihu Muslim, Kitaabur ru’ya, hadiith 2,266